15885. Jesu Ye Titi Aiye

1 Jesu ye, titi aiye
Eru iku ko ba ni mo;
Jesu ye; Nitorina
Isa oku ko n’ipa mo.
Alleluya!

2 Jesu ye; lat’oni lo
Iku je ona si iye;
Eyi y’o je ‘tunu wa
‘Gbat’ akoko iku ba de.
Alleluya!

3 Jesu ye; fun wa l’o ku
Nje Tire ni a o ma se;
A o f’okan funfun sin,
A o f’ ogo f’Olugbala.
Alleluya!

4 Jesu ye; eyi daju
Iku at’ipa okunkun
Ki y’o le ya ni kuro
Ninu ife nla ti Jesu
Alleluya!

5 Jesu ye; gbogbo ‘joba
L’orun, li aiye, di tire;
E je ki a ma tele,
Ki a le joba pelu Re.
Alleluya!

Text Information
First Line: Jesu ye, titi aiye
Title: Jesu Ye Titi Aiye
German Title: Jesu lebt, mit ihm auch ich
Author: Christian F. Gellert
Translator: Anonymous
Meter: 78.784
Language: Yoruba
Copyright: Public Domain
Tune Information
Name: ST. ALBINUS
Composer: Henry John Gauntlett
Meter: 78.784
Key: C Major
Copyright: Public Domain



Media
Adobe Acrobat image: PDF
MIDI file: MIDI
Noteworthy Composer score: Noteworthy Composer Score
More media are available on the tune authority page.

Suggestions or corrections? Contact us