Author: John H. Sammis; Anonymous Appears in 1 hymnal First Line: Gba t’a b’Oluwarin ninu ‘mole oro re Refrain First Line: Sa gbekele, ona miran kosi Lyrics: 1 Gba t’a b’Oluwarin ninu ‘mole oro re,
Ona wa yio ti ma mole to!
Gba t’a ban se’fe Re, on y’o ma ba wa gbe,
At’ awon t’o ba gbeke won le.
Egbe:
Sa gbekele, ona miran kosi
Lati layo n’nu Jesu, jupe k’a gbekele.
2 Ko s’ohun to le de, loke tabi nile
Tole ko agbara re l’oju;
Iyemeji a’teru, ibanuje, ekun
Kole duro b’a ba gbekele. [Egbe]
3 Ko s’eru t’ale ru, ko s’aro t’a le pin
Ti ki y’o san ere re fun wa
Kosi arokan mo, tabi ifajuro
Sugbon ibukun b’aba gbekele. [Egbe]
4 A ko le f’enu so b’ife re ti po to
Titi a o f’ara wa rubo
Aanu ti o nfihan, at’ayo t’o nfun ni
Je t’awon to ba gbeke won le. [Egbe]
5 Nibi ‘pade ayo ka joko ni ese Re.
Tabi kajo rin ni ona Re.
Oun to so la o se, ibi to wu la o lo;
Kosi beru, ka sa gbekele. [Egbe] Used With Tune: [Gba t’a b’Oluwarin ninu ‘mole oro re]
Sa Gbekele